explain-icon

Àlàyé

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye ọkan lara awọn okunfa ti o lè fun ajọṣepọ ati ifẹ lagbara laarin awọn onigbagbọ ododo, òun naa ni pe ti ẹnikẹni ba nífẹ̀ẹ́ arakunrin rẹ̀, ki o sọ fun un pe oun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ọla ti n bẹ fún ifẹ tó mọ́ kangá fun Ọlọhun Ọba Aleke ọla, tí kìí ṣe ifẹ nitori anfaani aye.
  • A fẹ ki a maa sọ fún ẹniti a nifẹẹ nitori Ọlọhun pé a nifẹẹ rẹ̀, kí ifẹ ati irẹpọ le maa lekun si.
  • Ìtànkálẹ̀ ifẹ laarin awọn onigbagbọ ododo maa n fún ìjẹ́ ọmọ iya ninu ẹsin lagbara ni, ó sì maa n dáàbò bo awujọ kuro nibi tútúká ati pinpin yẹlẹyẹlẹ.