explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbọ ti arákùnrin kan n gba ọmọ-ìyá rẹ ni imọran pe ki o fi àpọ̀jù itiju silẹ! O wa ṣàlàyé fun un pe ìtìjú wa ninu ìgbàgbọ́, ko si lee mu nǹkan kan wa ayafi oore. Ìtìjú jẹ iwa kan ti o maa n mu èèyàn ṣe dáadáa, ti o si maa n mu èèyàn fi ohun buruku silẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ohun ti o ba n ṣe idiwọ fun ẹ lati ṣe rere, a kii pe e ni ituju, ohun ti a maa n pe e ni ìdójútì, ati ikagara, ati ọ̀lẹ, ati ojo.
  • Ìtìjú Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn naa ni ki èèyàn maa ṣe ohun ti O pàṣẹ rẹ, ki èèyàn si fi àwọn nǹkan eewọ silẹ.
  • Ìtìjú ẹ̀dá naa ni ṣíṣe apọnle wọn, ki èèyàn si fi wọn si ipo wọn, ki èèyàn si jìnà si ohun ti o ba buru ni ti àṣà.