Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe ti ẹrú ti o gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ti o maa padà si ti wọn si maa san an ni ẹsan iṣẹ rẹ nibẹ, igbagbọ rẹ maa ṣe e ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe àwọn nǹkan yii: Akọkọ: Ọ̀rọ̀ dáadáa: Bii gbólóhùn SUBHAANALLAH ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati pipaṣẹ dáadáa, ati kikọ ibajẹ, ati ṣíṣe àtúnṣe láàárín àwọn èèyàn, ti ko ba wa ṣe e, ki o yaa dakẹ, ki o si ma fi suta kan èèyàn, ki o si ṣọ ahọ́n rẹ. Ìkejì: Ṣíṣe apọnle aládùúgbò: Pẹ̀lú ṣíṣe dáadáa si wọn, ati ki èèyàn si ma fi suta kan an. Ikẹta: Ṣíṣe apọnle àlejò ti n bọ láti ṣe abẹwo rẹ: Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dáadáa, ati fífún un ní oúnjẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.