explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe àwọn ti wọn n dajọ pẹ̀lú deede ati òdodo láàrin àwọn èèyàn ti wọn n bẹ lábẹ́ àṣẹ wọn ati idajọ wọn, ati ara ile wọn, wọ́n maa jókòó lori aga ti o ga ti wọn da latara imọlẹ, láti ṣe apọnle wọn ni ọjọ́ igbende. Ọwọ́ ọ̀tún Ọlọhun ni àwọn minbari yii maa wà, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ méjèèjì.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ọlá ti n bẹ fun deede ati ṣiṣenilojukokoro lori rẹ.
  • Deede kari gbogbo ìjọba ati idajọ láàrin àwọn èèyàn, titi dórí deede laarin awọn ìyàwó, ati awọn ọmọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
  • Ṣíṣe àlàyé ipò àwọn onideede ni ọjọ igbende.
  • Yiyatọ ipò àwọn onigbagbọ si ara wọn ni ọjọ́ igbende, onikaluku ni ibamu si iṣẹ rẹ ni.
  • Ọ̀nà ṣiṣenilojukokoro wa ninu awọn ọ̀nà ipepe ti maa n jẹ ki o wu ẹni tí a n pè lati tẹle ti Ọlọhun.