explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe iwa rere maa mu ẹni tí n wù ú de ipo ẹni tí n dunni mọ́ aawẹ ni ọsan ati idide fun ìjọsìn ni oru, ohun ti o ko nǹkan ti n jẹ iwa rere sinu ni: Ṣíṣe dáadáa, ati ọrọ rere, ati ìtújúká, ati ki èèyàn ma fi suta kan ẹlòmíràn, ati fifi ara da suta lati ọdọ àwọn èèyàn.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Titobi akolekan Isilaamu si títún ìwà ṣe, ati pípé rẹ.
  • Ọla ti n bẹ fun iwa dáadáa, titi ti ẹrú fi maa ti ara rẹ de ipo alaawẹ ti kii tú ẹnu, ati ẹni ti n dide fun ìjọsìn ni oru ti kii rẹ̀ ẹ́.
  • Gbigba aawẹ ni ọsan, ati idide ni oru jẹ iṣẹ ńlá ti inira wa ninu ẹ fun ẹ̀mí, ẹni tí ó ni iwa rere de ipo àwọn méjèèjì tori jija ẹ̀mí rẹ lógun pẹ̀lú ibalopọ dáadáa.