explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹni ti kii ba ṣàánú àwọn èèyàn, Ọlọhun ko nii ṣàánú rẹ, aanu ẹrú fún ẹ̀dá Ọlọhun jẹ ọkan ninu awọn okùnfà ti o tobi ju lati ri aanu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga gbà.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Àánú, nǹkan ti a n fẹ ni fun awọn ẹ̀dá yòókù, ṣùgbọ́n wọn dìídì dárúkọ àwọn èèyàn ni ti akolekan pẹ̀lú wọn.
  • Aláàánú ni Ọlọhun, O maa n ṣàánú àwọn ẹrú Rẹ ti wọn ni aanu, ẹ̀san maa n wa latara iran iṣẹ ni.
  • Aanu àwọn èèyàn kó mímú oore de ọdọ wọn sínú, ati titi aburu kuro fun wọn, ati bíbá wọn lò pọ̀ pẹlu dáadáa.