Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹ̀lẹ̀ ninu ọrọ ati ìṣe maa n lé àlámọ̀rí kún ni ẹwà ati pipe ati dídára, ohun ti o yẹ julọ ni ki ẹni ti ba n fi ẹ̀lẹ̀ ṣe nnkan o ri bukaata rẹ gbọ́. Àìsí ẹ̀lẹ̀ maa n ko àléébù ba àlámọ̀rí ni, ko si nii jẹ ki èèyàn o ri bukaata rẹ gbọ, ti o ba wa ri bukaata naa gbọ, o maa jẹ pẹlu inira ni.