explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe wa ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe dáadáa, ki èèyàn si ma fi oju kéré rẹ kódà ki o kéré, ninu ìyẹn ni tituju ka pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ nígbà tí a ba pade. O tọ́ fun Mùsùlùmí ki o ṣe ojúkòkòrò rẹ; tori ifi ara ro ọmọ-ìyá ti o jẹ Mùsùlùmí wa ninu ẹ, ati mimu ìdùnnú wọ inu rẹ̀.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ọla ti n bẹ fun ìfẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ, ati ẹ̀rín-músẹ́ ati ìtújúká ti wọn ba pade.
  • Pípé sharia ati kikari rẹ, ati pe o wa pẹlu gbogbo nǹkan ti àǹfààní ba n bẹ nibẹ fun awọn Mùsùlùmí ati ṣíṣe wọn ní ọ̀kan.
  • Ṣiṣenilojukokoro lori ṣíṣe dáadáa kódà ki o kéré.
  • A fẹ ki a maa dun àwọn Musulumi ninu; tori pe ìyẹn maa jẹ ki ìfẹ́ o wa laarin wọn.