Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé èèyàn ti o pe julọ ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dáa, bíi títú ojú ká, ati ṣíṣe dáadáa, ati ọ̀rọ̀ rere, ati ki èèyàn má fi sùtá kan ẹlòmíràn. Mumini ti o loore julọ ni àwọn ti wọn loore julọ fun awọn obinrin wọn, gẹgẹ bii ìyàwó rẹ, ati awọn ọmọbìnrin rẹ, ati awọn arábìnrin rẹ, ati awọn mọlẹbi rẹ lóbìnrin; torí pé àwọn ni wọn ni ẹtọ si iwa dáadáa ju ninu awọn èèyàn.