Annabi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ o máa ba npa wa lasẹ nkan mẹta ọtọtọ: Alakọkọ: ìbẹ̀rù Ọlọhun pẹlu pé kí a máa ṣe awọn nkan tí o jẹ ọranyan, àti gbígbé awọn nkan tí o jẹ èèwọ jù silẹ ní gbogbo ààyè àti àsìko àti ìṣesí, ní kọkọ àti ni gbangba, ni gbàá Alaafia àti àdánwò àti bẹ bẹ lọ. Ẹlẹẹkeji: tí o ba bọ sínú àìda kan, yaa ṣe iṣe daada kan lẹyìn rẹ; gẹgẹ bi kí ọ kirun, àti itọrẹ aanu, iṣe daada sí òbí àti iso òkun ẹbi pọ, àti itọrọ aforiji ẹsẹ -tàbí isiwọ kúrò níbi ẹsẹ- àti bẹ bẹ lọ, nitoripe dájúdájú eléyun yiò pàá àìda rẹ. Ẹlẹẹkẹta: Baa awọn ènìyàn lo pẹlu awọn iwā daada, bíi irẹrin musẹ sí wọn tàbí itujuka, àti ise pẹlẹ pẹlu wọn, àti rirọ pẹlu wọn, ati sise daada si wọn àti ikora dúró níbi fífi aburú kan wọn.