Ọ̀kan ninu awọn saabe- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- wá láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki o tọka òun si nǹkan kan tí o maa ṣe e ni anfaani, o wa pa a láṣẹ ki o ma maa bínú, itumọ ìyẹn ni pe ki o jìnnà si awọn okùnfà ti o le mu u binu, ki o si ko ara rẹ ni ìjánu ti ìbínú bá ṣẹlẹ̀, ki o ma tẹ síwájú nibi ibinu rẹ pẹlu pípa, tàbí lílù, tabi èébú, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Arákùnrin naa paara wíwá àsọtẹ́lẹ̀ naa ni ọpọlọpọ ìgbà, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko sọ fun un nibi àsọtẹ́lẹ̀ naa ju pe “ma ṣe maa binu”.