Ko si ninu ìwà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki o maa sọ̀rọ̀ buruku, tabi wu iwa burúkú, kii sii mọ̀ọ́mọ̀ ṣe e, o si jẹ oníwà ńlá. Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ pe: Dajudaju ẹni tí ó ni ọlá jù ninu yin ni ọdọ Ọlọhun ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, pẹlu ṣíṣe dáadáa, ati ìtújúká, ati ki èèyàn ma fi suta kan ẹlòmíràn, ati fifi ara da suta lati ọdọ ẹlòmíràn, ati rírò pẹ̀lú àwọn èèyàn pẹ̀lú dáadáa.