Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ nipa ọkunrin kan tí ó máa ń yá awọn eniyan ní owo gbese, tabi kí ó ta ọjà àwìn fún wọn, ó sì jẹ́ ẹniti o máa ń sọ fún ọmọ-ọdọ rẹ̀ tí o maa n lọ gba gbèsè tí awọn ènìyàn jẹ ẹ pé: Ti o bá dé ọdọ onigbese ti kò ní owo lati san gbese tó jẹ nitori ailagbara rẹ̀ "ṣamojukuro fun un"; bóyá ki o fun un ni akoko si, kí o sì ma sin in lagidi, tabi ki o gba ohun ti o wa ni ọwọ rẹ̀ naa, koda ki owo naa mai tii pe, o ṣe eleyii nitori pé ó ń fẹ́, ó sì n rankan pé kí Ọlọhun ṣamojukuro fun oun naa, ki O sì darijin oun, Nígbà ti ọkunrin yii kú, Ọlọ́hun dárí jìn in, Ó sì ṣamojukuro fun un nibi àwọn àṣìṣe rẹ̀.