explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe agbára gidi kii ṣe agbára ti ara, tabi ẹni ti o ba maa dá alágbára mìíràn mọ́lẹ̀. Alágbára gangan ni ẹni tí o ba ja ẹ̀mí rẹ lógun tí ó sì borí rẹ nígbà tí ìbínú rẹ bá n le; torí pé eyi n tọka si ikapa rẹ lori ẹmi ara rẹ ati ibori èṣù.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ọla ti n bẹ fun sùúrù ati ìdarí ẹ̀mí nígbà ìbínú, ati pe o wa ninu awọn iṣẹ rere ti Isilaamu ṣe wa ni ojúkòkòrò si.
  • Jija ẹ̀mí ni ogun nígbà ìbínú le koko ju jija ọ̀tá ni ogun lọ.
  • Isilaamu yi agbọye agbára ni asiko aimọkan padà si awọn iwa alapọn-ọnle, èèyàn ti o ni agbara ju ni ẹni tí ó ni ikapa ìjánu ẹ̀mí ara rẹ.
  • Jijina si ìbínú; tori ìnira ti o maa n fa fun ènìyàn kọ̀ọ̀kan ati àwùjọ.