explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ ki a maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ki a si ma fi ara ni wọn nibi gbogbo àlámọ̀rí ẹsin ati ayé, ìyẹn nibi ààlà nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni ẹtọ ti O si ṣe ni ofin. O n ṣeni lojukokoro lati maa fun wọn ni iro ìdùnnú nipa oore, ki a si ma le wọn sa kuro nibẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ojuṣe onigbagbọ ododo ni ki o jẹ ki awọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun, ki o si maa ṣe wọn ni ojúkòkòrò lati ṣe rere.
  • O tọ́ fun olupepe si ọdọ Ọlọhun ki o fi ọgbọ́n wo ọ̀nà ti yoo gba mu ipepe Isilaamu de ọdọ àwọn èèyàn.
  • Ifunni ni iro ìdùnnú maa n bi ìdùnnú ati ìkọjúsí ati ifọkanbalẹ fun olupepe ati fun nǹkan ti o n fi han àwọn èèyàn.
  • Ifi-ara-ni àwọn èèyàn maa n bi sísá, ati ìkọ̀yìnsí, ati mimu àwọn èèyàn maa ṣe iyèméjì nibi ọ̀rọ̀ olupepe.
  • Gbígbòòrò aanu Ọlọhun fun awọn ẹru Rẹ, ati pe O yọnu si ẹsin kan ti o rọrùn fun wọn, ati ofin ti wọn ṣe ni irọrun.
  • Ṣíṣe idẹkun ti wọn pàṣẹ rẹ naa ni ohun ti sharia mu wá.