Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe daadaa ni ọranyan le wa lori nibi gbogbo nǹkan. Dáadáa ni: Ìpayà Ọlọhun ni gbogbo ìgbà, níbi ìjọsìn fun Un, ati ṣíṣe oore, ati ki èèyàn má ṣe àwọn ẹ̀dá ni suta, ninu ìyẹn naa ni ṣíṣe dáadáa nibi pípa ati didu. Ṣíṣe dáadáa nibi pipa nigba ti a ba fẹ gba ẹsan: Pẹ̀lú sisẹṣa ọna ti o rọrun ju ti o si yára ju lati gba ẹ̀mí ẹni ti a fẹ pa. Ṣíṣe dáadáa nibi dídú nígbà tí a ba n dú nǹkan: Pẹ̀lú ṣíṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn pẹlu pípọ́n irinṣẹ naa, ki a si ma pọ́n ọn ni iwájú nǹkan ti a fẹ du ti o si n wò ó, ki a si ma dú u ni ibi tí ẹran-ọ̀sìn mìíràn wa ti o n wò ó.