Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si awọn kan ninu awọn ẹru Rẹ, Ninu wọn ni olupaya: Ẹni ti n tẹle àṣẹ Ọlọhun, ti n jìnnà si awọn nǹkan ti O kọ̀. O tun nífẹ̀ẹ́ si ọlọrọ: Ẹni ti o rọrọ̀ pẹ̀lú Ọlọhun kuro lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, kii ṣíjú wo ẹlòmíràn. O tun nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ó pamọ́: Ẹni ti o ni ìtẹríba, ti maa n sin Oluwa rẹ, ti n kó airoju pẹ̀lú nǹkan ti yóò ṣe é ni anfaani, ti kii ni akolekan si ki ẹni kan kan mọ oun, tabi ki wọn maa yin oun.