Láti ọ̀dọ̀ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni àwọn ife ìmumi odo adágún naa? O sọ pe: “Mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad wa lọ́wọ́ Rẹ bura, àwọn ife ìmumi rẹ pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ ni alẹ́ ti o ṣókùnkùn ti ko ni ẹsujo, àwọn ife imumi alujanna, ẹni tí o ba fi wọn mu omi, òùngbẹ ko tun gbẹ ẹ mọ láéláé, omi n dà sínú rẹ lati inú gọ́tà méjì nínú alujanna, ẹni tí ó bá mu nínú rẹ̀, òùngbẹ ko tun gbẹ ẹ mọ, ibu rẹ da gẹgẹ bii òró rẹ, gígùn rẹ ni odiwọn ohun ti n bẹ láàrin ìlú Hammaan si ìlú Aelah, omi rẹ̀ funfun ju wàrà lọ, o si dùn ju oyin lọ” O ni alaafia - Muslim gba a wa
explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- búra pe àwọn ife imumi odo adágún rẹ ni ọjọ igbende pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ, Iyẹn maa hàn ni oru ti o ṣókùnkùn ti ko si òṣùpá nínú ẹ; torí pé oru ti o ba ni òṣùpá, àwọn ìràwọ̀ rẹ ki i hàn; torí pé imọlẹ òṣùpá maa bo wọ́n mọlẹ, ati òru ti ko si ẹsujo nibẹ; torí pé bibẹ ẹsujo maa kọdi rírí àwọn ìràwọ̀, Ati pe àwọn ife imumi alujanna, ẹni tí ó bá mu omi inú rẹ ko nii gbẹ òùngbẹ láéláé, òùngbẹ ti o si maa gbẹ ẹ́ kẹ́yìn nìyẹn, Àti pé odo adágún rẹ, gọ́tà méjì lati inú alujanna n dà sínú rẹ, ìbú rẹ da gẹgẹ bii òró rẹ; Bákan náà ni àwọn origun odo adágún naa ṣe ri, gígùn rẹ maa ṣe déédéé ohun ti n bẹ laarin Hammaan, ìlú kan ni ti o wa ni ìpínlẹ̀ Balkọọhu ni ilẹ Shaam, titi dé Aelah, ilu kan ni ti a mọ ti o wa ni etí Shaam, Omi adágún naa funfun ju wàrà lọ, itọwo rẹ dùn ju oyin lọ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ifi odo adágún rinlẹ pe o n bẹ, ati awọn oríṣiríṣi idẹra ti o wa ninu ẹ.
  • Titobi odo adágún naa ati gigun rẹ ati ìbú rẹ ati pipọ àwọn ife imumi rẹ.