Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n bura lori sisunmọ sisọkalẹ Isa ọmọ Maryam- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- lati maa ṣe idajọ laaarin awọn eniyan pẹlu deedee pẹlu Sharia ti Muhammad, Ati pe o maa pada run agbelebuu ti awọn Nasara n gbe tobi, Atipe Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- maa pa ẹlẹ́dẹ̀, Ati pe Isa- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, o si maa jẹ ki gbogbo èèyàn wọnú Isilaamu. Ati pe dajudaju owo maa pada maa da ti ẹni kankan ko nii gba a; ìyẹn maa rí bẹ́ẹ̀ fun pipọ rẹ, ati rirọrọ gbogbo ẹni kọọkan pẹlu nnkan ti o n bẹ ni ọwọ rẹ mejeeji, ati sisọkalẹ alubarika ati itẹle-ara-wọn awọn oore.