Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju eyi ti o daa julọ ninu ọjọ ti oorun ran ninu rẹ ni ọjọ Jimọ, Ninu awọn iroyin rẹ ti o fi da yatọ ni pe: Dajudaju Ọlọhun ṣẹda Aadam- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ninu rẹ, ninu rẹ ni O mu u wọnu alujanna, ninu rẹ ni O mu u jade lati inu rẹ ti O si mu u sọkalẹ sori ilẹ̀, ọjọ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ.