explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fun, O maa fun un ni agbọye ninu ẹsin Rẹ, oun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si ni olupin, o maa n pin ohun ti Ọlọhun ba fun un ninu arisiki ati imọ ati awọn nǹkan mìíràn, ati pe ẹni ti n fúnni gan ni Ọlọhun, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n o kii ṣe olohun jẹ okùnfà ti ko lee ṣe anfaani kankan ayafi pẹ̀lú iyọnda Ọlọhun, ìjọ yii ko nii dẹkun lati maa duro lori àṣẹ Ọlọhun, ti ẹni tí ó bá yapa wọn ko si nii ko ìpalára ba wọn, titi ti ayé fi maa parẹ”

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Titobi ati ọla ti n bẹ fun imọ sharia ati kikọ ọ, ati ṣisẹnilojukokoro lori ẹ.
  • Diduro ti òdodo gbọdọ wa ninu ijọ yii, ti àwọn ikọ̀ kan ba ti pa á tì, àwọn ikọ̀ mìíràn maa dúró tì í.
  • Níní agbọye ninu ẹsin wa ninu pe Ọlọhun fẹ oore fun ẹrú rẹ.
  • Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n fúnni pẹ̀lú àṣẹ Ọlọhun ati fífẹ́ Rẹ, ati pe ko ni ikapa nǹkan kan.