explain-icon

Àlàyé

Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu Kuraani, wọn ko si nii bọ si ibòmíràn titi ti wọn fi maa kọ́ imọ ti o wa ninu awọn aaya mẹ́wàá yii ti wọn si maa lò ó, o maa waa ja si pe wọn kọ imọ ati iṣẹ papọ nìyẹn.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ọla ti n bẹ fun awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- ati ojúkòkòrò wọn lori kíkọ́ Kuraani.
  • Kíkọ́ Kuraani maa wáyé pẹ̀lú imọ ati lilo o, kii ṣe pẹ̀lú kika a ati hiha a nìkan.
  • Ìmọ̀ maa wáyé ṣiwaju ọ̀rọ̀ ati iṣẹ.