“Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ”

Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ”.
O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ ki a maa ka Kuraani nígbà gbogbo, ki a si maa tẹra mọ́ kika a ki èèyàn ma baa gbagbe rẹ lẹyin híhá a, o wa tẹnu mọ́ ọn pẹ̀lú ìbúra pe Kuraani yára kuro ninu àyà ju rakunmi ti a so lọ, oun naa ni eyi ti a fi okùn dè ni aarin ẹsẹ, ti eeyan ba n ka a nígbà gbogbo, o maa di i mu, ti o ba si tu u sílẹ̀, o maa lọ.

  1. Ti ẹni tí ó ha Kuraani ba tẹra mọ kika rẹ léraléra o maa wa ni hiha ninu ọkan rẹ, bi bẹẹ kọ yoo lọ ti yoo si gbagbe rẹ.
  2. Lara anfaani kika Kuraani nígbà gbogbo ni: Ẹ̀san, ati igbega ni ipò ni Ọjọ́ Àjíǹde.

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ