Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé wọn maa sọ fun ẹni ti n ka Kuraani, ti n lo ohun ti o wa ninu rẹ, ti n dunni mọ́ ọn ni kíkà ati híhá, ti o ba ti wọ alujanna- pé: Maa ka Kuraani, ki o si maa gòkè pẹ̀lú ìyẹn nibi awọn ipò alujanna, ki o si maa ke e gẹ́gẹ́ bí o ṣe maa n ke e ni aye pẹ̀lú pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ ati ifarabalẹ; tori pe ibùgbé rẹ n bẹ nibi opin aaya ti o maa kà.