Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pàápàá ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn ti o jẹ eewọ, oun naa ni: Sísọ nipa Mùsùlùmí ti ko si ni tòsí ohun ti o maa korira, bóyá o jẹ nibi awọn ìròyìn rẹ ti wọn dá mọ ọn tabi ti ìwà, gẹgẹ bii: Olojukan ẹlẹtan òpùrọ́, ati awọn nǹkan ti o jọ ọ ninu awọn ìròyìn ẹ̀gàn, kódà ki ìròyìn náà o wa lára rẹ. Ṣùgbọ́n ti iroyin naa ko ba si lara rẹ, eyi tun buru ju ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn lọ, oun ni BUHTAAN, itumọ rẹ ni: Adapa irọ mọ ọmọniyan pẹ̀lú nǹkan ti ko si lára rẹ.