'Uqbatu ọmọ 'Aamir ki Ọlọhun yọnu si beere lọwọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nipa Òkùnfà ti olugbàgbọ òdodo yóò fi ri àkóyọ láyé ati lọrun? Ni ojisẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Rẹ máa ba) wa sọ pé: nkan mẹta di ọwọ rẹ: Èkíní: ṣọ ahán rẹ kúrò níbi nkan ti kosi oore nibẹ, ati kúrò níbi gbogbo ọrọ aburu, ma se sọ ọrọ kan afi ko jẹ ọrọ daada. Ikeji: fìdí rẹ mọ ile rẹ ki o lè máa ṣe ìjọsìn fún Ọlọhun ni kọkọ (nigbati o ba da wa), gbaju mọ itẹle aṣẹ Ọlọhun Ọba to gbọngbọn ti o tun ga jùlọ, dáwà ninu ile rẹ lati sa fún wahala. Ikẹta: Máa sunkún ki o si máa ṣe àbámọ ki o si tuuba (tọrọ aforinjin ati iyọwọ kúrò) ni bi awọn ẹsẹ ti o ti ṣe kọja.