explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju nkan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ninu awọn iṣẹ ati awọn ọrọ ni iwa daadaa, ati pe ìyẹn n bẹ pẹlu titu oju ka, ati kika ṣuta kuro, ati ṣiṣe daadaa. Ati pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga korira ẹni ti ko dara nibi iṣe rẹ ati ọrọ rẹ, ẹni ti maa n fi ahọn rẹ sọ ibajẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ọla ti n bẹ fun iwa daadaa; nitori pe o maa n jogun ifẹ Ọlọhun fun ẹni ti ba n ṣe e, pẹlu ifẹ awọn ẹru Rẹ, ati pe oun ni o tobi julọ ninu nkan ti wọn o wọn ni ọjọ igbedide.