Ọmọ Mas’ud - ki Ọlọhun yọnu si i - n sọ pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ wọn ni khutubal haajah, oun ni wọn maa n sọ nibi ìbẹ̀rẹ̀ ọrọ nibi khutubah ati níwájú bukaata wọn, gẹgẹ bii khutubah igbeyawo ati khutubah irun Jimoh ati eyi ti o yatọ si wọn, Ati pe khutubah yii ko awọn ìtumọ̀ ti o tobi sinu bii alaye pe Ọlọhun lẹtọọ si gbogbo awọn iran ọpẹ, ati wiwa iranlọwọ lọdọ Rẹ ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, ati bibo awọn ẹṣẹ ati mimu oju kuro nibẹ, ati sisadi I kuro nibi gbogbo aburu, ati awọn aburu ẹmi ati eyi ti o yatọ si wọn. Lẹyin naa ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju imọna ọwọ Ọlọhun ni o wa, ẹni ti O ba fi mọna ko si oluṣini-lọna kan fun un, ẹni ti O ba ṣi lọna ko si atọnisọna kan fun un. Lẹyin naa o darukọ ijẹrii imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo pe oun ni pe ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, ati pe ijẹrii iṣẹ́-rírán ni pe dajudaju Muhammad jẹ ẹrusin Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ. O pari khutubah yii pẹlu awọn aayah mẹta ti wọn ko àṣẹ pẹlu ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sinu pẹlu ṣiṣe awọn àṣẹ Rẹ ati jijina si awọn nǹkan ti Ó kọ̀ lati fi wa oju rere Ọlọhun, ati pe dajudaju ẹsan ẹni ti o ba ṣe iyẹn ni dídára awọn iṣẹ ati awọn ọrọ ati pipa awọn aburu rẹ ati aforijin awọn ẹṣẹ ati iṣẹmi ti o mọ ni aye ati erenjẹ pẹlu alujanna ni ọjọ igbedide.