Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wọle tọ ọmọ-iya baba rẹ Abu Taalib ti o n pọka iku lọwọ, ni o wa sọ fun un pe: Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe "laa ilaaha illa Allāhu", gbolohun kan ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu, Ni Abu Jahli ati Abdullāh ọmọ Abu Umayyah wa sọ pe: Irẹ Abu Taalib, ṣe waa fi ilana baba rẹ Abdul Mutalibi silẹ ni? Oun si ni jijọsin fun awọn oriṣa, awọn mejeeji o si yẹ lẹni ti n ba a sọrọ titi ti o fi sọ ọrọ igbẹyin ti o ba wọn sọ pe: Lori ilana Abdul Mutalibi, ilana ẹbọ, ati jijọsin fun awọn oriṣa. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Maa ṣe adua aforijin fun ọ lopin igba ti Oluwa mi o ba ti kọ fun mi kuro nibẹ, ni gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ba sọkalẹ pe: {Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ, wọn ìbáà jẹ́ ẹbí, lẹ́yìn tí ó ti hàn sí wọn pé dájúdájú èrò inú iná Jẹhīm ni wọ́n} [Al Taobah: 113], Ni o wa sọkalẹ nipa Abu Taalib gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pe: ﴾Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà﴿ [Al Qaṣaṣ: 56], Dajudaju oo le fun ẹni ti o ba wu ẹ ni imọna, ati pe nkan ti o jẹ dandan fun ọ ni ki o jiṣẹ, ati pe Ọlọhun ni o máa n fi ẹni ti o ba wu U mọ ọna.