Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye diẹ ninu awọn ẹtọ Musulumi lori Musulumi ẹgbẹ́ rẹ̀, Àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí ni dídá salamọ padà si ẹniti ó bá salamọ si ọ. Ẹtọ keji: ṣiṣe abẹwo si alaaarẹ. Ẹtọ kẹta: Títẹ̀lé ìsìnkú láti ilé rẹ̀ titi de àyè ikirun si oku lara, titi de ibi saare rẹ̀, titi tí wọ́n ó fi sin in. Ẹtọ kẹrin: Dídáhùn ipepe bí ó bá pè é síbi àpèjẹ ìgbéyàwó àti awọn ǹkan mìíràn. Ẹtọ karùn-ún: Ṣiṣadura fun ẹniti ó bá sín, iyẹn ni pe kí ó sọ fun un nigba ti ó bá ti sọ pe ALHAMDULILLAH lẹyin sínsín: YARHAMUKALLAH, lẹyin naa ni ẹniti ó sín ó sọ pe: YAHDIKUMULLAHU WA YUSLIHU BAALAKUM.