Wọn bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Awọn iwa Isilaamu wo lo fi n lọla julọ? Ni o wa darukọ awọn iwa meji: Alakọkọọ: Pipọ ni imaa fun awọn alaini ni ounjẹ, ti saara ati ẹbun ati igbalejo ati ikolẹnujọ sì tun wọ inu rẹ, ati pe ọla ifunni l'ounjẹ tun kanpa ni awọn asiko ebi ati ọwọn gogo. Ẹlẹẹkeji ni: Sisalamọ si gbogbo musulumi, o mọ ọn ni tabi o ko tiẹ mọ ọn.