Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ṣo pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹni ti o n gun nkan ni o maa salamọ si ẹni ti o n rin, ẹni ti o n rin ni o máa salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti onka wọn kere ni wọ́n maa salamọ si awọn ti onka wọn pọ». Ati pe ninu Al-bukhari: «Ọmọde maa salamọ si agbalagba, ẹni ti o n rekọja maa salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti wọn kere maa salamọ si awọn ti wọn pọ». O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe itọsọna lọ sibi ẹkọ sisalamọ laarin awọn eeyan "As salaamu alaykum wa rahmotuLloohi wabarakātuHu". Ọmọde o wa salamọ si agbalagba, ẹni ti o n gun nkan o si salamọ si ẹni ti o n rin, ẹni ti o n rin o salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti onka wọn kere o salamọ si awọn ti onka wọn pọ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Jijẹ sunnah sisalamọ lori bi hadīth naa ṣe gbe e wa, ti ẹni ti o n rin ba salamọ si ẹni ti o n gun nkan ati eyiti o yatọ si ìyẹn ninu nkan ti wọn sọ yẹn, o lẹtọọ, sugbọn ìyẹn yapa si eyi ti o fi n lọla julọ.
  • Titan salamọ ka lori ọna ti o gba wa ninu hadīth naa ninu awọn okunfa ifẹ ati asopọ lo wa.
  • Ti wọn ba ṣe deedee ara wọn ti wọn ba ara wọn dọgba nibi nkan ti wọn darukọ yẹn, nigba naa ẹni ti o loore julọ ninu wọn ni ẹni ti o ba kọkọ salamọ.
  • Pipe ofin yii nibi ṣiṣe alaye gbogbo nkan ti ọmọniyan bukaata si.
  • Ikọni ni awọn ẹkọ Isilaamu ati fifun oni iwọ ni iwọ rẹ.