explain-icon

Àlàyé

Ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sin, o maa n: Akọkọ: O maa gbe ọwọ rẹ, tabi aṣọ rẹ sori ẹnu rẹ; ki nnkan kan ma baa jade lati ẹnu rẹ tabi imu rẹ ti o le ko suta ba alabajokoo rẹ. Ikeji: O maa n rẹ ohun rẹ nilẹ, ko si nii gbe e soke.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Alaye ilana rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi sinsin ati iwo awokọṣe rẹ nibi ìyẹn.
  • Ṣíṣe gbigbe aṣọ tabi inuju ati nnkan ti o jọ ọ sori ẹnu rẹ ni nnkan ti a fẹ ati sori imu rẹ ki nnkan kan ti o le ko suta ba alabajokoo rẹ ma baa jade lati ọdọ rẹ nigba ti o ba sin.
  • Irẹ ohun sinsin silẹ jẹ nnkan ti a fẹ, ó wa ninu pipe ẹkọ, ninu awọn iwa ti o daa si ni.