Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe afẹku Thābit ọmọ Qaysi – ki Ọlọhun yọnu si i – o wa beere nipa rẹ, ni arakunrin kan wa sọ pe: Maa mu iro rẹ wa fun ọ, ati idi ti o fi sa, ni o wa lọ si ọdọ rẹ ti o si ba a ni ẹni ti n banujẹ ti o si da ori kodo ninu ile rẹ, ni o wa bi i leere pe: Ki lo ṣe ọ? Ni Thābit wa sọ fun un nkan ti o ṣe e ninu aburu; latari pe oun maa n gbe ohun oun soke tayọ ohun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ti Ọlọhun si ti ṣe adun fun ẹni ti o ba ṣe iyẹn pẹlu bibajẹ iṣẹ rẹ, ati pe ninu awọn ọmọ ina ni yio wa. Ni arakunrin naa wa pada si ọdọ Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o si fun un niroo nipa iyẹn, ni Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa pa a laṣẹ ki o ṣẹri pada si ọdọ Thābit ki o si fun un ni iro idunnu wipe dajudaju ko si ninu awọn ọmọ ina, ṣugbọn o wa ninu awọn ọmọ alujanna, ati pe lilọ soke ohun rẹ iṣẹda rẹ ni, ati pe o jẹ agbẹnusọ fun Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o si tun jẹ agbẹnusọ fun awọn An-soor.