Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pé oun kéré nígbà tí oun n gun nǹkan ọ̀gùn pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa sọ pé: Mo maa kọ ẹ ni àwọn nǹkan kan ti Ọlọhun maa jẹ ki wọn ṣe ọ ni anfaani: Ṣọ́ Ọlọhun pẹlu ṣiṣọ àwọn àṣẹ Rẹ̀ ati jíjìnnà si awọn nǹkan tí O kọ̀, ki O maa ri ọ nibi itẹle àṣẹ Rẹ ati awọn iṣẹ ti a fi n sunmọ Ọlọhun, ki O si má ri ọ nibi awọn ìyapa ati ẹṣẹ, tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀san rẹ ni kí Ọlọ́run dáàbò bò ọ lọ́wọ́ nǹkan ìkórìíra ayé àti ọjọ́ ìkẹyìn, yoo sì ràn ọ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ rẹ níbikíbi tí o bá lọ. Ti o ba fẹ tọrọ nnkan, Ọlọhun nikan ni ki o bi; tori pe Oun nikan ni O maa n da onibeere lóhùn. Ti o ba fẹ iranlọwọ, Ọlọhun nìkan ni ki o wa iranlọwọ Rẹ̀. Ki o ni amọdaju pe anfaani kankan ko lee ṣẹlẹ̀ si ẹ kódà ki gbogbo àwọn ará ilẹ̀ kójọ lati ṣe ọ ni anfaani ayafi ohun ti Ọlọhun ba kọ fun ẹ, inira kankan ko si lee ṣẹlẹ̀ si ẹ kódà ki gbogbo àwọn ara ilẹ̀ kójọ láti fi ìnira kan ọ àyàfi ohun tí Ọlọhun ba ti kádàrá fun ẹ. Ati pe Ọlọhun ti kọ àlámọ̀rí yii, O si kádàrá rẹ ni ibamu si ọgbọ́n àti imọ Rẹ, ko si àyípadà fun nǹkan ti Ọlọhun kọ.