Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun kọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu awọn kadara awọn ẹda ni ifọsiwẹwẹ ninu isẹmi ati iku ati arisiki ati nnkan ti o yatọ si ìyẹn sinu Wàláà ti A n ṣọ ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun, ti yoo maa ṣẹlẹ̀ ni ibamu si nnkan ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ti kadara, Gbogbo nnkan ti o n bẹ n bẹ pẹlu idajọ Ọlọhun ati kadara Rẹ, Nnkan ti o ba ṣẹlẹ̀ si ẹru wọn ti kọ ọ pe ko nii fo o ru, nnkan ti o ba fo o ru wọn ti kọ ọ pe ko nii ṣẹlẹ̀ si i ni.