Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe gbogbo nnkan pẹ̀lú kádàrá ni; Titi dórí ikagara, oun naa ni: Gbígbé ohun ti o jẹ dandan láti ṣe jù silẹ ati dídá ìgbà si i ati lilọ ọ lára tayọ asiko rẹ, ninu ọrọ ayé ati ti alukiyaamọ. Ati ijafafa, oun naa ni: Ijafafa ati ọgbọ́n nípa àwọn àlámọ̀rí ayé àti alukiyaamọ. Ati pe Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ti kádàrá ikagara ati ijafafa ati gbogbo nǹkan, nǹkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ ni ayé àyàfi ki o ti ṣaaju ninu imọ Ọlọhun ati fifẹ Rẹ.