AbduLlaah ọmọ ‘Amr – ki Ọlọhun yọnu si i– sọ pe: Mo jẹ ẹni ti maa n kọ gbogbo nkan ti mo ba gbọ lẹnu ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ki n le baa de e mọlẹ pẹlu kikọ, ni awọn ọkunrin kan ninu Qurayshi ba kọ fun mi, wọn si sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – abara ni ti o maa n sọrọ ni asiko iyọnu ati ibinu, ti o si le ṣe aṣiṣe, ni mo ba dawọ duro nibi kikọ. Ni mo ba sọ fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nipa nkan ti wọn sọ, ni o wa na ọmọ ika rẹ si ẹnu rẹ o wa sọ pe: Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ ni ọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo ni eyikeyi ìṣesí ti ko baa jẹ, ati ni asiko iyọnu ati ibinu. Ati pe Ọba ti ọla Rẹ ga ti sọ nipa Anabi Rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- pe: {Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú * Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i} [An-Najmu 3-4].