explain-icon

Àlàyé

Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n sọ pe: Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọn si gbé e dìde nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún, o wa ni ilu Makkah fun ọdún mẹtala lẹ́yìn ìmísí, lẹyin naa ni wọn pa a láṣẹ lati ṣe hijra lọ sí ìlú Madina, o wa wa nibẹ fun ọdún mẹ́wàá, lẹyin naa ni o wa kú ni ọmọ ọdún mẹtalelọgọta.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Akolekan àwọn saabe si itan ìgbésí ayé Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).