Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ yiyi ibajẹ- oun ni gbogbo nnkan ti Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ kọ kuro nibẹ- pada, ni ibamu bi ikapa ba ṣe mọ, nitori naa ti o ba ri ibajẹ kan, yiyi i pada pẹlu ọwọ jẹ dandan fun un ti ikapa ba n bẹ fun un, ṣugbọn ti o ba kagara kuro nibi ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ pẹlu pe ki o kọ fun ẹni ti o ba ṣe e ki o si ṣàlàyé inira ti o n bẹ nibẹ fun un, ki o si tọ ọ sọ́nà lọ si ibi daadaa dipo aburu yii, Tí o ba kagara kuro nibi ipo yii, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ pẹ̀lú ki o korira ibajẹ yii, yoo si ni ipinnu pe ti oun ba ni ikapa lori yiyi i pada ni ko ba ṣe bẹẹ, Yiyi pada pẹlu ọkan jẹ eyi ti o lẹ julọ ninu awọn ipo igbagbọ nibi yiyi ibajẹ pada.