Lati ọdọ Abu Bakr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo pe ẹyin eniyan, ẹ maa n ka aayah yìí: (Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀na), mo si gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: "Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi, ti wọn ko si gba a mu ni ọwọ rẹ mejeeji, o sunmọ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari wọn". O ni alaafia - Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati Ibnu Maajah ati Ahmad
explain-icon

Àlàyé

Abu Bakr As-Sideeq- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe: Dajudaju awọn eniyan a maa ka aayah yìí: (Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀na)(Al-Maa'ida: 105). Ti wọn maa wa gbọye ninu rẹ pe dajudaju igbiyanju jẹ dandan lori ọmọniyan lori titun ara rẹ ṣe nikan, ati pe ìṣìnà ẹni ti o ṣina ko nii ko inira ba a lẹyin ìyẹn, ati pe wọn ko wa lati ọdọ wọn pipáṣẹ daadaa ati kikọ iwa ibajẹ! ni o wa fi mọ wọn pe ko ri bayẹn, pe oun gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa a- n sọ pe: Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi ti wọn ko si kọ fun un kuro nibi abosi ṣíṣe rẹ, ti agbara lori kikọ fun un si n bẹ lọdọ wọn, ó maa ku díẹ̀ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari gbogbo wọn, ẹni ti o n ṣe ibajẹ ati ẹni ti o n dakẹ nipa rẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ojúṣe awọn Musulumi ni gbigba ara wọn ni imọran, ati pipaṣẹ daadaa ati kikọ ibajẹ.
  • Iya Ọlọhun ti gbogboogbo maa kari alabosi fun ṣíṣe abosi rẹ, o si maa kan ẹni ti o dakẹ lori titako o ti o si ni ikapa lori titako o.
  • Kikọ gbogbo eniyan ati imu wọn gbọ́ awọn aayah Kuraani ye ni ọna ti o ni alaafia ti o wa fun wọn.
  • Àbójútó jẹ dandan fun ọmọniyan lati ni agbọye iwe Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-, ti ko fi nii gbọ ọ ye ni ọna ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko gba lero.
  • Imọna ko nii ṣẹlẹ̀ pẹlu gbigbe pipaṣẹ daadaa ati kikọ ibajẹ silẹ.
  • Alaye ti ó tọna fun aayah náà ni: Ẹ dunni mọ sisọ ẹmi ara yin kuro nibi awọn ẹṣẹ, ti ẹ ba ti sọ ẹmi ara yin, anù ẹni ti o ba sọnu ko nii ko inira ba yin ti ẹ ko ba ni ikapa lati pàṣẹ daadaa ati lati kọ ibajẹ, pẹlu ṣíṣe awọn nnkan èèwọ̀ ti ẹ ba ti mọna lọ sibi jijina si i.