Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- gba apakan wa ninu bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe maa n kirun, o wa sọ pe ti o ba fẹ kirun, o maa n kabara nigba ti o ba dide fun kabara wiwọ irun, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba n lọ si rukuu, ati nigba ti o ba fẹ forikanlẹ, ati nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, ati nigba ti o ba forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹlẹẹkeji, ati nigba ti o ba gbe ori rẹ dide kuro nibẹ, ati nigba ti o ba dide lati rakah meji akọkọ lẹyin ti o ba jokoo fun ataya akọkọ nibi irun oni rakah mẹta tabi oni rakah mẹrin, lẹyin naa o maa n ṣe bẹẹ nibi gbogbo irun pata titi o maa fi pari rẹ, o maa n sọ ti o ba ti gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu pe: Sami’alloohu liman hamidaHu, lẹyin naa o maa n sọ ti o ba wa ni iduro pe: Robbanaa wa laKal hamdu. Lẹyin naa Abu Huraira maa n sọ ti o ba ti pari irun pé: Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju ẹmi ni ìrun mi jọ irun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jù, bi o ṣe maa n kirun nìyí titi o fi fi aye silẹ.