Awọn ọkunrin kan wa ba ọkan ninu awọn saabe, ti wọn n bi i leere nipa minbari ti Anabi ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n lo: latara nnkan wo ni wọn ti ṣe e? Wọn ti ba ara wọn jiyan ti wọn ti ba ara wọn fa a lori ìyẹn, ni o wa sọ fun wọn pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ranṣẹ si arabinrin kan ninu awọn Ansar ti o ni ọmọ-ọdọ kan ti o jẹ kafinta, o wa sọ fun un pé: Pa ọmọ-ọdọ rẹ láṣẹ lati kan minbari kan fun mi ti maa maa jokoo le lori nigba ti mo ba n ba awọn eniyan sọ̀rọ̀, ni arabinrin naa ba da a lohun, o wa pa ọmọ-ọdọ rẹ láṣẹ lati ṣe minbari kan fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- latara igi ti n jẹ TỌRFAAHU, nigba ti o pari arabinrin naa ba fi ranṣẹ si Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o ba gbe e wa, ni wọn ba gbe e kalẹ si aaye rẹ ninu mọsalasi, lẹyin naa ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kirun lori rẹ ti o si kabara ti o si wa lori rẹ, lẹyin naa o rukuu ti o si wa lori rẹ, lẹyin naa o sọkalẹ ti o n rin lọ si ẹyin lai yi oju rẹ si ọgangan ẹyin, ni o wa forikanlẹ sibi isalẹ minbari, lẹyin naa o ṣẹri pada, nigba ti o pari irun o dojukọ awọn eniyan, o wa sọ pe: Ẹyin eniyan, dajudaju mo ṣe eyi ki ẹ le maa tẹle mi ki ẹ si kọ irun kiki mi.