Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- ni ataya ti wọn maa n ka lori irun, o wa fi ọwọ rẹ si ọwọ rẹ mejeeji, lati jẹ ki o kọ ibi ara si i. Gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ ọ ni Surah ninu Kuraani ninu nnkan ti o tọka lori iko akolekan Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si ataya yii ni gbolohun ati ni ìtumọ̀. O si sọ pe: "At-tahiyyaatu lillah": Oun ni gbogbo ọrọ ati iṣẹ ti o da lori igbetobi, gbogbo ẹ ni o tọ si Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn. "As-solawaatu": Oun ni ìrun ti a mọ, ọran-anyan rẹ ati awọn nafila rẹ jẹ ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. "At-toyyibaatu": Òun ni awọn ọrọ ati awọn iṣẹ ati awọn iroyin ti wọn daa ti wọn si n da lori pipe, gbogbo rẹ tọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. "As-salaamu alaika ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu": Adura ni o jẹ fun un pẹlu lila kuro nibi gbogbo aleebu ati nnkan ti a koriira, ati alekun ati ọpọlọpọ ninu gbogbo oore. "As-salaamu alaina wa 'alaa'ibaadillahis soliheen": Adura ni o jẹ pẹlu ọlà fun olukirun ati fun gbogbo ẹru rere ni sanmọ ati ilẹ. "Ash-hadu an laa ilaaha illallohu": O n túmọ̀ si pe mo n fi i rinlẹ ni ifirinlẹ ododo pẹlu rẹ pe ko si ẹni ti a le jọsin fun lododo afi Ọlọhun. "Wa anna Muhammadan 'abduHu wa rosuuluHu": Mo n fi ijẹ ẹru ati ìránṣẹ́ ti o jẹ opin rinlẹ fun un. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe olukirun lojukokoro lati ṣe ẹṣa ninu adura ti o ba fẹ.