Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ kuro nibi awọn alamọri mẹẹrin kan: Alakọkọọ rẹ: Kikọ fun obinrin kuro nibi ṣiṣe irin-ajo ọjọ meji lai si pẹlu ọkọ rẹ tabi ẹnikan ninu awọn eleewọ rẹ oun naa ni ẹni ti wọn ṣe fifẹ ẹ (ọmọbinrin naa) ni eewọ fun un ni ṣiṣe leewọ gbere ninu awọn alasunmọ-ọn, gẹgẹ bii ọmọ ati baba, ọmọkùnrin ọmọ-iya rẹ ọkunrin ati ọmọkùnrin ọmọ-iya rẹ obinrin, ati ọmọ-iya baba rẹ l'ọkunrin ati ọmọ-iya iya rẹ l'ọkunrin, ati awọn to jọ bẹ́ẹ̀. Ẹlẹẹkeji rẹ: Kikọ kuro nibi gbigba aawẹ ọjọ ọdun itunu ati ọjọ ọdun ileya, ki baa ṣe pe musulumi gba mejeeji ni gbigba ti ẹ̀jẹ́, tabi aṣegbọrẹ, tabi itanran. Ẹlẹẹkẹta rẹ: Kikọ kuro nibi kiki irun naafila lẹyin irun Asri titi ti oorun o fi wọ, ati lẹyin yiyọ aarọ titi ti oorun o fi yọ. Ẹẹkẹrin rẹ: Kikọ kuro nibi ṣiṣe irin-ajo lọ si aaye kan ninu awọn aaye ati nini adisọkan ọla rẹ ati nini adisọkan pe adipele ẹsan wa nibẹ yatọ si awọn masalasi mẹta, nitori naa a ko gbọdọ di ẹru irin-ajo lọ si ibi ti o yatọ si wọn lati lọ kirun nibẹ, torí pé dajudaju adipele o ni maa ba ẹsan ayaafi ni awọn masalasi mẹta yii, masalasi abeewọ (kahbah), ati masalasi Anabi, ati masalasi aqsa.