Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ayé pẹ̀lú nǹkan ti n bẹ ninu ẹ jẹ nǹkan ti eeyan maa n gbádùn fun ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn naa ni o maa kúrò, ati pe ìgbádùn rẹ ti o ni ọlá jù ni obìnrin rere, eyi ti o ṣe pe ti o ba wo o yoo dun un ninu, ti o ba pa a láṣẹ yoo tẹle e, ti ko ba si ni tòsí o maa ṣọ́ ọ ninu ẹ̀mí ara rẹ ati dúkìá rẹ.