Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju aye dun nibi itọwo, o si tutu nibi riri, ti ọmọniyan maa gba ẹtanjẹ pẹlu rẹ ti yoo si tẹ̀rì sinu rẹ ti yoo si sọ ọ di eyi ti o tobi julọ ninu ironu rẹ. Ati pe dajudaju Ọlọhun- mimọ ni fun Un- fi awọn kan ninu wa role fun awọn kan ni igbesi aye yìí, ki O le maa wo bi a ṣe maa ṣiṣẹ, njẹ a maa tẹle E, tabi a maa yapa Rẹ? Lẹyin naa, o sọ pe: Ẹ ṣọ́ra ki igbadun aye ati ọṣọ rẹ ma tan yin jẹ, ti o wa maa mu yin gbe nnkan ti Ọlọhun pa yin láṣẹ rẹ ju silẹ, ati kiko si nnkan ti O kọ kuro fun yin nibẹ. Ati pe ninu nnkan ti o jẹ dandan julọ lati ṣọ́ra kuro ninu rẹ ninu awọn wahala aye ni wahala obinrin, ati pe o jẹ akọkọ wahala ti awọn ọmọ Ísírẹ́lì ko síbẹ̀.