Anọbi - kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - joko lẹ ori minbari ni ọjọ kan ti mbá awọn ọmọ lẹyìn rẹ sọrọ, o si ṣọ pe: dájúdájú eyí ti o pọ ti mo nbẹru tí mo sì npáya fún nípa yin lẹyin mi ni ohun tí wọn yóò ṣi silẹ fún yin nínú àwọn ìbùkún ilẹ ati aye ati ọsọ rẹ àti ẹwà rẹ ati awọn orisirisi igbadun ati aṣọ ati awọn irúgbìn àti awọn nkan míran ti awọn eniyan ma fi nse iyanran àti akọ to un ti pé isẹku rẹ kéré. Ni arákùnrin kan bá sọ pé: ọsọ aye idẹra lo jẹ láti ọdọ Ọlọhun, se idẹra yi yoo tun pada di iya ati ìbáwí ni bi?! ni awọn eniyan ba bu onibeere naa nigbati wọn ri pe Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Re máa ba a) dakẹ ti kò sọrọ, wọn ro pé oti mu Anọbi binu ni. O padà wá hàn pé dájúdájú Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ngba waayi kuraani lọ wọ (Kuraani nsọ kalẹ fun) o wa bẹrẹ síní nu oogun ojú rẹ kúrò, o wa sọ pé: onibeere náà dà? O sọ pé: emi ni. Anọbi dupẹ fún Ọlọhun o si fi iyin fun, leyin náà ni o sọ pé: oore gangan koni mu nkan wa ju oore lọ, ṣugbọn nkan yindin won yi kii se oore pọnbele nítorí awọn wahala ati ifiga gbága lórí rẹ ati igbaju mọ ti kii jẹ ki a le gbaju mọ ọrun ni pípé, lẹyin naa ni o wa se àpèjúwe rẹ, o sọ pé: dájúdájú irúgbìn iṣẹ palẹ ojo ati titutu rẹ; òhun ni iru irúgbìn kan ti aa ma wu ewurẹ tabi àgùntàn lati jẹ ẹ, ti o bá jẹ pẹlu parahan ati wọbia yóò pa tabi ko fẹ pa a, ayaafi ẹran ti o jẹ ewé tutu yi ti ẹgbẹ kan inu rẹ bá ti kun yóò fi yoku silẹ, leyin náà yóò kọjú sí òòrùn lati sinmi, yóò jagbẹ yóò tó bẹẹ ni yóò gbé awon eyi to kù ni enu rẹ mi, lẹyìn naa yóò tún padà sí bẹ lati jẹ. dájúdájú dukiya yi bi ewéko to tutù daada ni ti o si dùn, ọpọ rẹ le pani tabi ki o fẹẹ pani; ayaafi ti o ba jẹ diẹ ti o ni bukaata si ti yóò sì tó ní ọna ẹtọ, irú bẹ ko nii mu ìnira lọwọ, idẹra musulumi ohun ni ẹnití o bá aláìní ati ọmọ orukan ati onírinàjò ninu rẹ, ẹnití o bá gbà pẹlu ẹtọ rẹ wọn yóò fi ibukún si fun, ẹni tí o bá gba a láì ṣe pẹlu ẹtọ rẹ àpèjúwe rẹ o dà gẹgẹ bi ẹnití njẹ un tiko yó, yóò padà jẹ ibalẹjo fún un ni ọjọ igbende.