Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa awọn eeyan kan ti wọn n ṣe ibajẹ ninu dúkìá àwọn Musulumi, ti wọn si n mu u ni ọ̀nà ti kò tọ́, eyi ni itumọ kan ti o kari nibi dukia, nibi kiko o jọ lati ibi ti ko ti ni ẹtọ, ati nina an sibi ti kii ṣe aaye rẹ ti o tọ, jíjẹ dúkìá àwọn ọmọ orukan maa wọ inú ẹ, àti awọn dúkìá ti a fi sọri awọn kan, ati titako agbafipamọ, ati mimu ninu dúkìá gbogbogboo ni ọ̀nà tí kò tọ́. Lẹ́yìn náà ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé ẹsan wọn ni iná ni Ọjọ́ Àjíǹde.