Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fun wa pé dajudaju awọn ìrun ọ̀ranyàn wakati maraarun lojoojumọ, irun Jimọ ni gbogbo ọsẹ, gbigba aawẹ oṣu Ramadan ni gbogbo ọdun, ó máa n pa awọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké tí eniyan bá dá laarin wọn rẹ́ ni, pẹlu majẹmu pé kí eniyan jìnnà si awọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá, àmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá, gẹgẹ bii ṣìná àti ọtí mímu, wọn kò nii pa a rẹ́ àyàfi kí eniyan túúbá kúrò níbẹ̀ kó sì ronúpìwàdà.